15890. Lai Lodo Oluwa

1 "Lai lodo Oluwa!"
Amin, beni k’o ri,
Iye wa ninu oro na,
Aiku ni titi lai,
Nihin ninu ara,
Mo sako jina si;
Sibe alale ni mo nfi,
Ojo kan sunmole!

2 Ile Baba loke,
Ile okan mi ni;
Emi nfi oju igbagbo
Wo bode wura re!
Okan mi nfa pipo,
S’ ile na ti mo fe,
Ile didan t’ awon mimo
Jerusalem t’ orun.

3 Awosanma dide,
Gbogbo ero mi pin;
Bi adaba Noa, mo nfo
Larin iji lile.
Sugbon sanma kuro,
Iji si rekoja,
Ayo ati alafia
Si gba okan mi kan.

4 L’ oro ati l’ ale
L’ osan ati l’ oru,
Mo ngbo orin orun, bori
Rudurudu aiye,
Oro ajinde ni,
Hiho isegun ni,
Lekan si, "Lai lod’ Oluwa."
Amin, beni ko ri.

Text Information
First Line: "Lai lodo Oluwa!"
Title: Lai Lodo Oluwa
English Title: Forever with the Lord
Author: James Montgomery
Translator: Anonymous
Language: Yoruba
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: NEARER HOME
Composer: Isaac Woodbury
Harmonizer: A. S. Sullivan
Meter: SMD
Key: A Major
Copyright: Public Domain



Media
Adobe Acrobat image: PDF
MIDI file: MIDI
Noteworthy Composer score: Noteworthy Composer Score
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us