15905. Oluwa Mi, Mo Njade Lo

1 Oluwa mi, mo njade lo,
Lati se ise ojo mi;
Iwo nikan l’emi o mo
L’oro l’ero, ati n’ise.

2 Ise t’o yan mi, l’anu Re
Je ki nle se tayotayo;
Ki nr’oju Re ni ise mi,
K’emi si le f’ife Re han.

3 Dabobo mi lowo ’danwo,
K’o pa okan mimo kuro
L’owo aniyan aiye yi,
Ati gbogbo ifekufe.

4 Iwo t’oju Re r’okan mi,
Ma wa low’otun mi titi,
Ki mm sise lo l’ase Re,
Ki nf’ise mi gbogbo fun O.

5 Je ki nreru Re t’o fuye
Ki mma sora nigbagbogbo;
Ki mma f’oju si nkan t’orun,
Ki nsi mura d’ojo ogo.

6 Ohunkohun t’o fi fun mi
Je ki nle lo fun ogo Re
Ki nfayo sure ije mi
Ki mba O rin titi d’orun.

Text Information
First Line: Oluwa mi, mo njade lo
Title: Oluwa Mi, Mo Njade Lo
Author: Charles Wesley
Translator: Anonymous
Meter: LM
Language: English
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: WARRINGTON
Composer: Ralph Harrison
Meter: LM
Key: B♭ Major
Copyright: Public Domain



Media
Adobe Acrobat image: PDF
MIDI file: MIDI
Noteworthy Composer score: Noteworthy Composer Score
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us